Ezekiel 21:28-32

28 a“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nípa àwọn ará Ammoni àti àbùkù wọn:

“ ‘Idà kan idà kan
tí á fa yọ fún ìpànìyàn
tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò
àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!
29Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a rí èké nípa yín
àti àfọ̀ṣẹ èké nípa yín
a yóò gbé e lé àwọn ọrùn
ènìyàn búburú ti a ó pa,
àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé,
àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.

30“ ‘Dá idà padà sínú àkọ̀ rẹ̀
Níbi tí a gbé ṣẹ̀dá yín,
ní ibi tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ wá.
31Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín,
èmi o sì fi èémí ìbínú gbígbóná
mi bá yín jà.
32Ẹ̀yin yóò jẹ́ èpò fún iná náà,
a yóò ta ẹ̀jẹ̀ yin sórí ilẹ̀ yín,
a kì yóò rántí yín mọ́;
nítorí èmi Olúwa ní ó ti wí bẹ́ẹ̀.’ ”
Copyright information for YorBMYO